Details
Mo láyọ̀ láti fi tó yín létí pé Jọlá àti Oyínkán ti parí sáà ẹ̀kọ́ kan ní 23/1/2025. Ní sáà ẹ̀kọ́ tó parí náà, àwọn ohun tí wọ́n kọ́ ni orúkọ àwọn ibìkan àti àwọn ohun ìrìnsẹ̀, wọ́n si ṣe ọ̀pọ̀lọpọ̀ ìkúrọ̀sọ nípa wọn, mo sì ní àrídájú pé èyí ran ọ̀rọ̀ síṣọ wọn lọ́wọ́. Wọ́n kọ́ oríṣi àwọn ìhun èdè tí a máa ń lò nínú ìtàkúrọ̀sọ láti so gbólóhùn papọ̀, a sì lò wọ́n láti ṣe ọ̀pọ̀lọpọ̀ ìkúrọ̀sọ. Wọ́n kọ́ díẹ̀ lára àwọn ọ̀rọ̀ tó nííṣe pẹ̀lú ojú ọjọ́ àti àsìkò, a ṣe àtúnyẹ̀wò ẹ̀kọ́ lórí òǹkà...